10. Nípa oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọ́run tí fi fún mi, gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n ọ̀mọ̀lé, mo ti fi ìpìlẹ̀ ilé lélẹ̀, ẹlòmíràn sì ń mọ lé e, ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù kíyèsára bí yóò ṣe mọ ọ́n lé e.
11. Nítorí kò sí ẹlòmíràn tó le fi ìpìlẹ̀ tòótọ́ mìíràn lélẹ̀ ju èyí tí a fi lélẹ̀ àní Jésù Kírísítì ni ìpìlẹ̀ náà.
12. Ǹjẹ́ bí ẹnikẹ́ni bá fí wúrà, fàdákà, òkúta olówó-iyebiye, igi, koríko, àgékù koríko mọ lé orí ìpìlẹ̀ yìí.
13. Iṣẹ́ olúkúlùkù ènìyàn yóò hàn, nítorí ọjọ́ náà yóò fi í hàn, nítorí pé nínú iná ni a ó ti fi hàn, iná náà yóò sì dán irú iṣẹ́ èyí tí olùkúlùkú ṣe wò.
14. Bí iṣẹ́ tí ẹnikẹ́ni bá ṣe lórí rẹ̀ bá dúró, òun yóò sì gba èrè rẹ̀.
15. Bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni bá jóná, òun yóò pàdánù: Ṣùgbọ́n òun tìkárarẹ̀ ni a ó gbàlà, ṣùgbọ́n bí ìgbà tí ènìyàn bá la àárin iná kọjá.
16. Ṣé ẹ̀yin kò tilẹ̀ mọ̀ pé tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́? Pé Ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín?
17. Bí ẹnikẹ́ni bá ba tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run jẹ́, òun ni Ọlọ́run yóò parun; nítorí pé mímọ́ ni tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run, èyí tí ẹ̀yín jẹ́.