1 Kíróníkà 9:13-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Àwọn àlùfáà, tí wọ́n jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀sán ó dín méjì (1,760). Wọ́n jẹ́ alágbára ọkùnrin, tí wọ́n lè dúró fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú ilé Ọlọ́run.

14. Níti àwọn ará Léfì:Ṣémáíà ọmọ Hásíhúbì, ọmọ Ásíríkámù, ọmọ Háṣábíà ará Mérárì:

15. Bákíbákárì, Héréṣì, Gálálì àti Mátaníyà, ọmọ Míkà, ọmọ Ṣíkírì, ọmọ Ásáfù;

16. Ọbadíà ọmọ Ṣémáíà, ọmọ Gálálì, ọmọ Jédútúnì; àti Bérékíà ọmọ Ásà, ọmọ Élíkánà, Tí ó ń gbé nínú àwọn ìlú àwọn ará Nétófá.

17. Àwọn Olùtọ́jú Ẹnu Ọ̀nà:Ṣálúmù, Ákúbù, Tálímónì, Áhímánì àti arákùnrin wọn, Ṣálúmì olóyè wọn,

1 Kíróníkà 9