1 Kíróníkà 6:61-64 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

61. Ìyòókù àwọn ìran ọmọ Kóháhítì ní a pín ìlú mẹ́wá fún láti àwọn ìdílé ní ti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè.

62. Àwọn ìran ọmọ Géríṣómù, sí ìdílé ni a pín ìlú mẹ́talá fún láti ẹ̀yà àwọn ẹ̀yà Íṣákárì, Áṣérì àti Náfítalì, àti láti apá ẹ̀yà Mánásè tí ó wà ní Básánì.

63. Àwọn ìran ọmọ Mérárì, ìdílé sí ìdílé, ní a pín ìlú méjìlá fún láti ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Gádì àti Ṣébúlúní.

64. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún àwọn ará Léfì ní ìlú wọ̀nyí pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.

1 Kíróníkà 6