17. Gbogbo wọ̀nyí ni a kà nípa ìtàn-ìdílé, ní ọjọ́ Jótamù ọba Júdà, àti ní ọjọ́ Jéróbóámù ọba Ísírẹ́lì.
18. Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àti àwọn ọmọ Gádì, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, nínú àwọn ọkùnrin alágbára tí wọ́n ń gbé aṣà àti idà, tí wọ́n sì ń fi ọrun tafà, tí wọ́n sì mòye ogun, jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ènìyàn o le ẹgbẹ̀rinlélógún dín ogójì, tí ó jáde lọ sí ogún náà.
19. Wọ́n sì bá àwọn ọmọ Hágárì jagun, pẹ̀lú Jétúrì, àti Néfísì àti Nádábù.
20. Nígbà tí wọ́n sì rí ìrànlọ́wọ́ gbà si, a sì fi àwọn ọmọ Hágárì lé wọn lọ́wọ́, àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn; nítorí ti wọn képe Ọlọ́run ní ogun náà, òun sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn; nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e.
21. Wọ́n sì kó ẹran ọ̀sìn wọn lọ; ràkunmí ẹgbàámẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n àti àgùntàn ọ̀kẹ́ méjìlá ó lé ẹgbàárùnún, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbàá, àti ènìyàn ọ̀kẹ́ márùn ún.