1 Kíróníkà 4:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwọn ọmọ Júdà:Fárésì, Hésírónì, Kárímì, Húrì àti Ṣóbálì.

2. Réáíà ọmọ Ṣóbálì ni baba Jáhátì, àti Jáhátì baba Áhúmáyì àti Láhádì. Àwọn wọ̀nyí ni ẹ̀yà ará Ṣórà.

3. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Étanílù:Jésírélì, Ísímà, Ídíbásì, orúkọ arábìnrin wọn sì ni Sélélípónì

4. Pénúélì sì ni baba Gédórì, àti Édérì baba Húṣà.Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Húrì, Àkọ́bí Éfúrátà àti baba Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.

1 Kíróníkà 4