1 Kíróníkà 24:6-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ṣémáíà ọmọ Nétanélì, akọ̀wé ọ̀kan lára àwọn ọmọ Léfì sì kọ orúkọ wọn níwájú ọba àti àwọn ìjòyè: Ṣádókù Àlùfáà, Áhímélékì ọmọ Ábíátarì àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà tí a mú láti ọ̀dọ̀ Éléásári àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ Ítamárì.

7. Ìpín èkíní jáde sí Jéhóíáríbù,èkejì sí Jédáià,

8. Ẹlẹ́kẹta sì ni Hárímù,ẹ̀kẹ́rin sì ní Ṣéórímù,

9. Ẹ̀karùn-ún sì ni Maíkíyà,ẹlẹkẹ́fà sì ni Míjámínì,

10. Ẹ̀kẹ́je sì ni Hakósì,ẹlẹ́kẹ́jọ sí ni Ábíjà,

11. Ẹkẹ́sàn sì ni Jésúà,ẹ̀kẹ́wà sì ni Ṣékáníà,

12. Ẹ̀kọ́kànlá sì ni Élíásíbù,ẹlẹ́kẹjìlá sì ni Jákímù,

13. Ẹ̀kẹtàlá sì ni Húpà,ẹlẹ́kẹrìnlá sì ni Jéṣébéábù,

14. Ẹkẹdógun sì ni Bílígà,ẹ̀kẹ́rìndílogún sì ni Ímerì

1 Kíróníkà 24