1 Kíróníkà 23:30-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

30. Wọ́n sì gbọdọ̀ dúró ní gbogbo òwúrọ̀ láti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa. Wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe irú kan náà ní àsálẹ́.

31. Ní gbàkúgbà ẹbọ ọrẹ sísun ni wọ́n fi fún Olúwa ní ọjọ́ ìsinmi àti ní àsìkò oṣù tuntun àti ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì tí a paláṣẹ. Wọ́n gbọdọ̀ sìn níwájú Olúwa lójojúmọ́ ní iye tó yẹ àti ní ọ̀nà tí a ti paláṣẹ fún wọn.

32. Bẹ́ẹ̀ ni nígbà náà, àwọn ọmọ Léfì gbé ìgbékalẹ̀ jáde fún ìpàdé àgọ́, fún ibi mímọ́ àti, lábẹ́ àwọn arákùnrin àwọn ọmọ Árónì fún ìsìn ilé Olúwa.

1 Kíróníkà 23