1 Kíróníkà 15:5-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ọgọ́fà nínú àwọn ọmọ Kóhátì;Úríélì olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀.

6. Igba ó lé ogún nínú àwọn ọmọ Mórárì;Ásaíà olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀.

7. Àádóje nínú àwọn ọmọ Gésóní;Jóẹ́lì olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀.

8. Igba nínú àwọn ọmọ Élísáfálì;Ṣémáíà olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀.

9. Ọgọ́rin nínú àwọn ọmọ Hébírónì;Élíélì olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀.

10. Méjìléláàdọ́fà nínú àwọn ọmọ Húsíélì;Ámínádábù olórí àti àwọn ẹbí Rẹ̀.

11. Dáfídì sì ránṣẹ́ pe Ṣádókù, Ábíátarì tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, àti Úríélì, Ásáíà. Jóẹ́lì, Ṣémáíà, Élíélì àti Ámínádábù tí wọ́n jẹ́ Léfì.

1 Kíróníkà 15