1 Kíróníkà 12:24-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Ọkùnrin Júdà, gbé àṣà àti ọ̀kọ̀, ẹgbẹ̀ta lé lọ́gọ́rin (6,080) tí ó ti di ìhámọ́ra fún ogun;

25. Àwọn ọkùnrin Símónì, akọni tó mú fún ogun sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin;

26. Àwọn ọkùnrin Léfì ẹgbàájì ó le ẹgbẹ̀ta (4,600),

27. Pẹ̀lú Jéhóíádà, olórí ìdílé Árónì pẹ̀lú ẹgbẹ̀ẹ́dógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ènìyàn (3,700),

28. Àti Sádókì akọni ọ̀dọ́mọkùnrin, pẹ̀lú àwọn (22) méjìlélógún ìjòyè láti ọ̀dọ̀ àwọn ìdílé Rẹ̀;

29. Àwọn arákùnrin Bẹ́ńjámínì ìbátan ọkùnrin Ṣọ́ọ̀lù ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000), ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹni tí ó si kù ní olóòtọ́ sí ilé Ṣọ́ọ̀lù títí di ìgbà náà;

30. àwọn arákùnrin Éfúráímù, ògbójú akọni, ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n nílé baba wọn ẹgbàwá ó le ẹgbẹ̀rin (20,800)

31. Àwọn ọkùnrin nínú ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, tí a yàn nípa orúkọ láti wá àti láti yan Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba-ẹgbàásàn (18,000).

32. Àwọn ọkùnrin Ísákárì, àwọn ẹni tí ó mọ ìgbà yẹn ó sì mọ ohun tí Ísírẹ́lì yóò se ìgbà (200) àwọn ìjòyè, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìbátan wọn lábẹ́ òfin wọn.

1 Kíróníkà 12